Ohun ti o je wa l'ogun julo ni wipe ki a te awon onibara wa lorun
nipa sise ohun-èlò ero oloye komputa ti o wulo nidede, lai dawoduro ati laijafira.
Titewo gba ibeere fun atunse ati iyípadà eto ise, pàápàá ni asale
ise idagba soke na. Awon igbésê ise yio lo agbára iyipada wonyi fun anfani ati igbesoke oro-aje awon onibara wa.
Pipese awon ojulowo ohun-èlò ero oloye komputa lati tete de odo awon onibara wa
larin ose meji sii osu meji, ni akoko ti o kúrúju, laijafira.
O se pataki fun awon onisowo ati awon ti o se agbateru ise ohun-èlò ero oloye komputa yi lati jo maa sise
papo lojojumo ati nigbagbogbo, jaleyika igbero ise na.
Ao se eto igbero ise yi yika awon osise fun ìwúríìmóríyá olúkúlùkú.
Ao fi won si ayika tio dara, ao si fun won ni atilehin ati iranlowo
lati le ni igbekele pe won yio se ise ni kiakiai ati pelu iyari.
Ona ti o níyôrísí ati idaniloju julo
lati fi iroyin ohun ti o nsele to awon osise ohun-èlò ero olóye kompútà
leti ni nipa ipade ati si so oro ni ojukoro.
Osuwon ilosiwaju ti o se pataki ju ni pipese ohun-èlò ero oloye komputa ti o wulo.
Igbese ona ti a le fi se ise ti o joju ni ki ibasepo ni ilosiwaju.
Awon igilehin ogba nipa inawo, awon agbateru ati awon ti on lo irinse ohun-èlò ero oloye komputa yii gbodo maa jo sise papo ni igbagbogbo, ki ibasepo ti o dan moran bale wa ni aarin won.
Amojuto ise takun takun, imo
ati apere to peye yio mu ki ise tubo lerelori.
O se pataki lati ri daju wipe ise aseti ati asedanu dinku.
Akojopo osise ti o le se etò lẹ́sẹsẹ ni won le mu apẹrẹ
ati ohun tí a fê jade ni ona ti o dara julo.
Loore koore, awon alajosepo yio se ayewo bi
ise won se tun le níyôrísí, won awa tò ise won lẹ́sẹsẹ
lati le se atunse ìhùwàsi ati akojopo won bi o se to ati bi o se ye.